BÍ ÌKÍNI ṢE Ń DÍNKÙ NÍ ILẸ̀ YORÙBÁ — ṢÉ A TI N PADANÙ ÌBỌ̀WỌ̀ FÚN ÀGBÀ?
Glow FM Podcasts S1 E1 Full

ASA ATI ISE NI ILE YORUBA

BÍ ÌKÍNI ṢE Ń DÍNKÙ NÍ ILẸ̀ YORÙBÁ — ṢÉ A TI N PADANÙ ÌBỌ̀WỌ̀ FÚN ÀGBÀ?

Nínú àṣà Yorùbá, ìkíni àti ìbọ̀wọ̀ fún àgbà jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ tí a fi ń dá ọmọ rere mọ̀. Láyé àtijọ́, ọmọ Yorùbá máa ń kí àgbà nígbà tó bá rí i, ó sì máa ń fi ìwà pẹ̀lẹ́ àti ìrẹ̀lẹ̀ hàn. Ṣùgbọ́n lónìí, ó dà bí ẹni pé àṣà yìí ń dínkù díẹ̀díẹ̀. Ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ kò tún kí àgbà bíi ti ìgbàanì, àwọn kan sì lè kọjá lẹ́gbẹ̀ẹ́ àgbà láì kí i. Kí ni ó fa ìyípadà yìí? Ṣé ìgbésí ayé òde òní, ìmọ̀ ẹ̀rọ, ilé ẹ̀kọ́, tàbí ìyípadà nínú bí àwọn òbí ṣe ń tọ́ àwọn ọmọ ṣe ló fa á? Nínú episode yìí ti ÀṢÀ ATI IṢẸ́ ILẸ̀ YORÙBÁ, a máa jíròrò: • Ìtumọ̀ ìkíni nínú àṣà Yorùbá. • Ìdí tí Yorùbá fi ń fi ọ̀wọ̀ pàtàkì fún àgbà. • Bí àwọn ọmọ ṣe ń kí àwọn àgbà ní ìgbàanì. • Kí ló dé tí ìkíni fi ń dínkù láàárín àwọn ọ̀dọ́ lónìí? • Ipa tí àwọn òbí àti ilé ṣe nínú kíkọ́ ìwà àti ìbọ̀wọ̀. • Ipa social media àti àṣà òde òní lórí ìwà Yorùbá. • Ṣé a lè tún ìwà ìkíni àti ìbọ̀wọ̀ padà sí àwùjọ wa? • Kí ni àwọn ọ̀dọ́ àti àwọn àgbà lè ṣe láti dá àṣà yìí sílẹ̀ fún ìran tó ń bọ̀?

17:12 0 plays 0 downloads

Watch

Episode video

About this episode

Show notes

Ìbéèrè pàtàkì: Ṣé o rò pé àwọn Yorùbá ń padanu àṣà ìkíni àti ìbọ̀wọ̀ fún àgbà? Kí ni ìwọ fúnra rẹ̀ ti rí?

Listener discussion

Comments (0)

Timestamps are available for audio episodes.
No comments yet. Be the first to share your thoughts.